AYE L’OJA

AYE L’OJA

Aye yi je oja ati pelu ona irin ajo fun gbogbo eda. Oja je ibi ti gbogbo eniyan nfi owo ati oja won han. Boya oro yi lema ye o nipa alaye yi sugbon un o salaye ni kikun ki to pari oro yi. Abi eniyan sinu aye yi ni akoko, igba ati pelu fun ipinu, yala okunrin tabi obirin ipinu wa fun iseda. Iran yio wa saye fun imuse ipinu Eleda ni akoko yi, iwo eda gbodo mu ipinu iseda re se gege bi ayanmo ninu aye. Aye yio ma je oja gege bi owe ile alawo dudu ti so, nigbati ile-basu patepate lomaku. Nje o mo, iwo ohun kawe yi wipe ojo igba aye re nsunmo le bi o ti ndagba si gege bi atipo laye, oja lowa sugbon dandan ni ki o pada losi le. Nje o ti mura lati losi ile? Nje o ti e ni ireti ati ri ile naa? Nje iwo tilemura tabi gbaradi fun ile naa? Nje iwo tile mo ile ibiti iwo nlo gan? Nitiori ojo ori ki se ewo fun iku laye, iku kise idiwom fun ojo ori, ojo ori koni agbara lati da iku duro, beni! Ki se gbogbo eniyan loma dagba tabi darugbo ninu aye yi gege bi oja ti ni ipele re. awon oja miran nta warawara lodidi lodidi be sini awon oja miran wa labode fun iwulo ti won. Opolopo eya orile ede yio wa naa ja fun idikan ati fun lilo won. Ki e si magbagbe wipe awon olosa. Awon arenije ati awon oni jibiti pelu wa loja lati wa je oja fun ere buburu.

Bibi omo saye dara tabi bibi awon omo saye dara sugbon bawo ni asele mo boya awon omo naa yio dagba? Bawoni asele mo boya imuse wa ninu irin ajo omo naa lati mu idi ti a se bi saye se, a ngbe ile aye ti a koreti awon ohun buburu to sele si eniyan. Nigbati aba ronu jinle gidigidi nipa se igbesi aye wa gege bi anaja ninu aye oowo sise ninu aye wa. Ojo ori eniyan papa nsoro isiro idagba soke oja ti o wa naa laye. Aye yi ki se ibugbe eniyan beni ki se ti eda eniyan sugbon oja ni, iwo nikan ko lowa loja yi fun owo sise, opo lejijo wa ninu isowo oja yi gege bi onisowo ti o nreti ere jije. Opo loti koja lo kuro ninu oja yi ati won si ti losi ile won lajule orun, sugbon ni boni ile re wa? Bi o ti wa loja gege bi alaye, orun rere ni tabi orun apadi jowo pinu loni akoko yio pinnu re lowo re gege bi alaye okan. Ti o koba yipa daa kuro ninu iwa buburu, iwa ibaje, iwa imotara eni nikan, iwo yio gbeyin irinajo re si orun egbe. Mase kuro tabi dawo ire ni sise duro, igbinyanju rere yio mu o de orun rere. Ade atono si ile ologo fun o naa ni Jesu Kristi ati iye re. Laisi Jesu Kristi ki o mo wipe o ko le se aseyori ninu irin ajo ojo re laye. Jesu Kristi ni ona ati iye ti o losi ile Ologo lati oja yi, gbaa laye ninu irin-ajo ati oja, ki o si jewo awon ese buburu inu okan re fun loni. Ba Eleda re laja loni yipada kuro ninu iwa buburu bi o ti ngba Jesu Kristi laye yio gba o kuro ninu oko aye re ti satani tiri sinu omi aye, iwo ki o seleya, Jewo gbogbo re fun loni, ola le peju, yio si dara fun o bi o ti se eyi, wa ile ijosin ti Bibeli lagbegbe re ki ore-ofe re maa fo o ruu. Alafia o!

Bibeli kika: Isaiah 43:7; 2 Kor. 10:31; Johannu 15:1-8; Effsu 2:1-10; Johannu 3:7; Johannu 19:1-30; Rom. 6:23; 2 Tim. 3: 15-17

Fun Imoran Ati Adura Kan Si Wa Ni

Plot 1 – 7, MorningStar Avenue, MorningStar Bus Stop, Tanmola CDA, PowerLine, Abe Koko,  Owode Yewa South  L. G., Ogun State.

apostolic.ng, prophetic.ng, apostleakanbi.org

apostolic@EagleStar.ng,prophetic@EagleStar.ng, counseling@EagleStar.ng

+234 802 397 3464, +234 705 666 1960

Ipade Arin Ose Ati Ti Osusu

Ojo Isinmi: Isin Ifinhan: 8:00 am – 12:00 pm

Ojo isegun: Eko Lase Ese Re:  – 5:20 pm – 7:00 pm

Ojo Boo: Wakati Ti o Gbona: – 5:20 pm – 7:00 pm

Ojo Abameta: Isin Iri Owuro: – 6: 00 am – 7: 00 am

Ojo Isinmi Ti O Gbeyin Ninu Osu: Isin Ifami Ororo Yan Ati Idupe – 8:00 am – 12 pm

Ojo Eti Ti O Gbeyi Ninu Osu: Orun ifihan Ati Ona Abayo 12: pm

Ojo Ti O Gbeyin Ninu Osu: Oru Esodu Ati Irekoja Si Osu Titun 11: 30 pm

Jesu Kristi wa laye!



Adura Igbagbo Abadi

  1. Oluwa Olodumare Olorun Anu ibere aye ati opin Orunn iba Re ni gbogbo ohun to o fi Nje Eledab ibere opin.
  2. Iwalaye Re gba akoso agbegbe mi bi mo ti woo inu adura loo ni oruko Jesu Kristi.
  3.  Oluwa mi fun mi ni agbara igbani lati gbagba yori gbogbo adura.
  4. Gbogbo emi okunkun ati eniyan irinse adanu ninu aye mi e pora loni nipa ase oruko Jesu.

GBADURA PELU ORIN DAFIDI 30, ISAYA 15, OWE 24 ATI FILIPI 4

  1. Oluwa, modupe l’owo Re fun jije Eni ti ngbe talaka dide lati inu atan, lati joko pelu awon omo alade.
  2. Oluwa, modupe l’owo Re fun awon majemu okunkun ti E ti baje lori aiye mi.
  3. Emi Mimo, je ki akoko mi de, ni oruko Jesu.
  4. Ojurere ti mo ma fi tayo ju egbe lo, ba le mi l’ori, ni oruko Jesu.
  5. Ina Oluwa, la ipile mi koja, ipile mi ko gbodo ba aiye mi je, ni oruko Jesu.
  6. Emi Mimo, yanda agbara ibori Re l’ori aiye mi, ni oruko Jesu.
  7. Ina Emi Mimo, ro aiye mi l’agbara fun ise takuntakun, ni oruko Jesu.
  8. Awon owo ati omo ika mi setan ogun nigba kugba, ni oruko Jesu.
  9. Orun mi, gbo ohun Olorun, o ni wo ni oruko Jesu.
  10. Afefe iwosan, fe l’ori awon alaisan ni ile-iwosan ati ni ile, ni oruko Jesu.
  11. Oluwa, so awon ota mi di elenga niwaju mi, ni oruko Jesu.
  12. Gbogbo agbara iboju ota l’ori aiye mi, e pa run,
    ni oruko Jesu.
  13. Gbadura ninu Emi fun ogbon iseju(30 min.)